We Believe JesusFé, Esperança e Nova Vida

Isaiah 22

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · iorubá

← Isaiah 21 Isaiah Isaiah 23 →

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.

2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,

3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;

4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:

5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan

6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,

7Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,

8Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.

9Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi

10Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu

11Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì

12Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

13Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;

14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé

17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí

18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì

19Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,

20“Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.

21Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.

22Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.

23Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.

24Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.

25“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

← Isaiah 21 Isaiah Isaiah 23 →

Isaiah 22 — iorubá:

Biblica® Open Nkanda wu Moyo, Nguizani Yimona ayi Minkunga 2002