We Believe JesusFé, Esperança e Nova Vida

Saamu 136

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · iorubá

← Saamu 135 Saamu Saamu 137 →

1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;

2Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

3Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

4Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

5Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

6Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

7Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

8Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

9Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

10Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;

11Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;

12Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

13Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;

14Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀

15Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;

16Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já

17Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;

18Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

19Sihoni, ọba àwọn ará Amori

20Àti Ogu, ọba Baṣani;

21Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

22Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,

23Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

24Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

25Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

26Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

← Saamu 135 Saamu Saamu 137 →

Saamu 136 — iorubá:

Biblica® Open Nkanda wu Moyo, Nguizani Yimona ayi Minkunga 2002