1Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé,
2“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ,
3níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi,
4Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
5Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre;
6Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́;
7“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú,
8Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,
9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,
10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?
11“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run:
12Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i;
13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;
15Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:
16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,
17àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;
18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,
19Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́,
20Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn;
21Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ;
22Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí;
23Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí,