1Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé,
2“Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
3Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
4Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
5“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
6Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
7Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
8Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
9Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
10Ó fi ìdè yí omi òkun ká,
11Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
12Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
13Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
14Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;