1Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé,
2“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
3Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
4Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
5Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú,
6“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
7Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
8Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
9Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
10Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,
12Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
13àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
14Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
15“Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
16Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
17Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi;
18“Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
19Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
20Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
21ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
22“Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,