1Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé,
2“Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,
3Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin;
4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà
6Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;
7“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,
8Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,
9Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé,
10Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà,
11Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí
12Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,
13“Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára;
14Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́;
15Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ;
16Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;
17Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò
18Ó tú ìdè ọba
19Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò
20Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò
21Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá
22Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá
23Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;
24Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,
25Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀;