1Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé,
2“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?
3Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?
4Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘Ìṣe mi jẹ́ aláìléérí,
5Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,
6kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ,
7“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?
8Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?
9Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,
10“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà
11Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;
12Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n
13“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,
14bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù
15nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,
16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ;
17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
19Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
20Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;