1Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi
2Háà, èmi ìbá ní ni aginjù
3Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀
4“Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;
5Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni
6Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn;
7Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;
9Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”
10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè
11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì
12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.
15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
18Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,
19A gbọ́ igbe ìpohùnréré
20Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa;
21Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé
22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
23Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
24Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:
25“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.
26Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”