We Believe JesusFé, Esperança e Nova Vida

Sekariah 5

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · iorubá

← Sekariah 4 Sekariah Sekariah 6 →

1Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò.

2Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”

3Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀.

4Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”

5Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.”

6Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”

7Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè, obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òsùwọ̀n.

8Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òsùwọ̀n, ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀.

9Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀, wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òsùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run.

10Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òsùwọ̀n náà lọ.”

11Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè Babeli láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”

← Sekariah 4 Sekariah Sekariah 6 →

Sekariah 5 — iorubá:

Biblica® Open Nkanda wu Moyo, Nguizani Yimona ayi Minkunga 2002