1Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
2Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
4Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
5Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
6Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
7Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
8Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
9Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
10Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
11Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
12Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
13Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
14Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
15Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
16Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
17Òkú kò lè yìn Olúwa,
18Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa