1Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
2Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
3Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
4Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
5Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
6Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
7Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
8Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
9Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,
10nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
11Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
12nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
13Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
14nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
15Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
16Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
17Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
18Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
19Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
21Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
22Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
23Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
24Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
25Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
26Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
27Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
28Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
29Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
30Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
31Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
32Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
33Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
34Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
35Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,