1Jobu sì dáhùn ó si wí pé,
2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,
3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,
4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
7Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,
8“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;
9Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,
10Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,
11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?
12Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?
13Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:
14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,
15Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé
16Tí ó dúdú nítorí omi dídì,
17Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,
18Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,
19Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,
20Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;
21Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;
22Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,
23Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,
24“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́
25Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó
26Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe
27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,
28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.
29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;
30Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?