1Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
2Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
3Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
4Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
5Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
7Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
8Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
9Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
11Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
12Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
14Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
15àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
16Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà,
17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
19Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
20Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
21Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase